Isaiah 26:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n ti kú, wọn kò ní wà láàyè mọ́, ẹ̀mí wọn kò ní dìde mọ́ ní isà òkú. Nítorí bẹ́ẹ̀ ni o ṣe jẹ wọ́n níyà, o sì pa wọ́n run, o sì ti sọ gbogbo ìrántí wọn di ohun ìgbàgbé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn okú, nwọn kì yio yè; awọn ti ngbe isà-okú, nwọn kì yio dide; nitorina ni iwọ ṣe bẹ̀ wọn wò ti o si pa wọn run, ti o si mu ki gbogbo iranti wọn parun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n ti kú báyìí, wọn ò sí láàyè mọ́; gbogbo ẹ̀mí tí ó ti kọjá lọ wọ̀nyí kò le dìde mọ́. Ìwọ jẹ́ wọ́n ní ìyà o sì sọ wọ́n di asán, Ìwọ pa gbogbo ìrántíi wọn rẹ́ pátapáta.