Isaiah 26:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí aboyún tí ó fẹ́ bímọ, tí ó ń yí, tí ó sì ń ké ìrora, nígbà tí àkókò àtibímọ rẹ̀ súnmọ́ tòsí bẹ́ẹ̀ ni a rí nítorí rẹ, OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gẹgẹ bi aboyun, ti o sunmọ akoko ibi rẹ̀, ti wà ni irora, ti o si kigbe ninu irora rẹ̀; bẹ̃li awa ti wà li oju rẹ, Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó lóyún tí ó sì fẹ́rẹ bímọ tí í rúnra tí ó sì ń sunkún nínú ìrora rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwa rí níwájúu rẹ OLÚWA.