Isaiah 26:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
A wà ninu oyún, ara ń ro wá, a ní kí a bí, òfo ló jáde. A kò ṣẹgun ohunkohun láyé bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń gbé ayé kò tíì ṣubú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awa ti loyun, awa ti wà ni irora, o si dabi ẹnipe awa ti bi ẹfũfu; awa kò ṣiṣẹ igbala kan lori ilẹ, bẹ̃ni awọn ti ngbe aiye kò ṣubu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwa wà nínú oyún, a wà nínú ìrora ṣùgbọ́n, afẹ́fẹ́ ni a bí lọ́mọ. Àwa kò mú ìgbàlà wá sí ilẹ̀ ayé; àwa kọ́ ni a bí àwọn ènìyàn tí ó wà láyé.