Isaiah 26:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn òkú wa yóo jí, wọn óo dìde kúrò ninu ibojì. Ẹ tají kí ẹ máa kọrin, ẹ̀yin tí ó sùn ninu erùpẹ̀. Nítorí pé ìrì ìmọ́lẹ̀ ni ìrì yín, ẹ óo sì sẹ ìrì náà sì ilẹ̀ àwọn òkú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn okú rẹ yio yè, okú mi, nwọn o dide. Ẹ ji, ẹ si kọrin, ẹnyin ti ngbe inu ekuru: nitori ìri rẹ ìri ewebẹ̀ ni, ilẹ yio si sọ awọn okú jade.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n àwọn òkúu yín yóò wà láàyè ara wọn yóò dìde. Ìwọ tí o wà nínú erùpẹ̀, dìde nílẹ̀ kí o sì ké igbe ayọ̀. Ìrì rẹ dàbí ìrì òwúrọ̀, ayé yóò bí àwọn òkúu rẹ̀ lọ́mọ.