Isaiah 26:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA óo yọ láti ibùgbé rẹ̀, láti fi ìyà jẹ àwọn tí ń gbé inú ayé, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ilẹ̀ yóo tú ẹ̀jẹ̀ àwọn tí wọ́n pa sórí rẹ̀ jáde, kò sì ní bo àwọn tí a pa mọ́lẹ̀ mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina, kiye si i, Oluwa ti ipò rẹ̀ jade lati bẹ̀ aiṣedede ẹniti ngbe ori ilẹ wo lori ilẹ; ilẹ pẹlu yio fi ẹ̀jẹ rẹ̀ hàn, kì yio si bo okú rẹ̀ mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kíyèsíì, OLÚWA ń jáde bọ̀ láti ibùgbé e rẹ̀ láti jẹ àwọn ènìyàn ilẹ̀ ayé ní ìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ẹ wọn. Ayé yóò sì sọ àwọn ẹ̀jẹ̀ tí a ta sí oríi rẹ̀, kì yóò sì fi àwọn tí a ti pa pamọ́ mọ́.