Isaiah 27:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí ìlú olódi ti di ahoro, ó di ibùgbé tí a kọ̀ sílẹ̀, tí a sì patì bí aginjù; ibẹ̀ ni àwọn ọmọ mààlúù yóo ti máa jẹko, wọn óo dùbúlẹ̀ níbẹ̀, wọn óo sì máa jẹ àwọn ẹ̀ka igi rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ilu-olodi yio di ahoro, a o si kọ̀ ibugbé silẹ, a o si fi i silẹ bi aginju: nibẹ ni ọmọ-malu yio ma jẹ̀, nibẹ ni yio si dubulẹ, yio si jẹ ẹka rẹ̀ run.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìlú olódi náà ti dahoro, ibùdó ìkọ̀sílẹ̀, tí a kọ̀tì gẹ́gẹ́ bí aṣálẹ̀; níbẹ̀ ni àwọn ọmọ màlúù ti ń jẹko níbẹ̀ ni wọn ń sùn sílẹ̀; wọn sì jẹ gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ tán.