Isaiah 27:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ẹ̀ka igi náà yóo dá nígbà tí wọ́n bá gbẹ, àwọn obinrin yóo sì fi wọ́n dáná. Nítorí òye kò yé àwọn eniyan wọnyi rárá; nítorí náà, ẹni tí ó dá wọn kò ní ṣàánú wọn, Ẹni tí ó mọ wọ́n kò ní yọ́nú sí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati ẹka inu rẹ̀ ba rọ, a o ya wọn kuro: awọn obinrin de, nwọn si tẹ̀ iná bọ̀ wọn: nitori alaini oye enia ni nwọn: nitorina ẹniti o dá wọn kì yio ṣãnu fun wọn, ẹniti o si mọ wọn kì yio fi ojurere hàn wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ gbẹ, a kán wọn dànù àwọn obìnrin wá wọ́n, sì fi wọ́n dáná nítorí àwọn ènìyàn tí òye kò yé ni wọ́n jẹ́; Nítorí náà ni Ẹlẹ́dàá wọn kò ṣe yọ́nú sí wọn. Ẹlẹ́dàá wọn kò sì síjú àánú wò wọ́n.