Isaiah 27:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo pa ẹ̀yin eniyan Israẹli bí ẹni pa ọkà, láti odò Yufurate títí dé odò Ijipti, yóo sì ko yín jọ lọ́kọ̀ọ̀kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe li ọjọ na, Oluwa yio ja eso kuro ni ibu odò si iṣàn Egipti, a o si ṣà nyin jọ li ọkọkan, ẹnyin ọmọ Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ náà OLÚWA yóò sì kó ooré láti ìṣàn omi Éúfírétì wá títí dé Wádì ti Éjíbítì, àti ìwọ, ìwọ ọmọ Ísírẹ́lì, ni a ó kójọ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.