Isaiah 27:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ náà, a óo fun fèrè ogun ńlá, àwọn tí ó ti sọnù sí ilẹ̀ Asiria ati àwọn tí a lé lọ sí ilẹ̀ Ijipti yóo wá sin OLUWA lórí òkè mímọ́ ní Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe li ọjọ na, a o fun ipè nla, awọn ti o mura lati ṣegbe ni ilẹ Assiria yio si wá, ati awọn aṣátì ilẹ Egipti, nwọn o si sìn Oluwa ni oke mimọ́ ni Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti ní ọjọ́ náà, a ó fun fèrè ńlá kan. Gbogbo àwọn tí ń ṣègbé lọ ní Ásíríà àti àwọn tí ń ṣe àtìpó ní Éjíbítì yóò wá sin OLÚWA ní òkè mímọ́ ní Jérúsálẹ́mù.