Isaiah 27:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọ̀nà tí a fi lè pa ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu rẹ́, tí a fi lè mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kúrò ni pé: Kí ó fọ́ gbogbo òkúta àwọn pẹpẹ oriṣa rẹ̀ túútúú, bí ẹfun tí a lọ̀ kúnná; kí ó má ku ère oriṣa Aṣera tabi pẹpẹ turari kan lóòró.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina nipa eyi li a o bò ẹ̀ṣẹ Jakobu mọlẹ: eyi si ni gbogbo eso lati mu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ kuro; nigbati on gbe okuta pẹpẹ kalẹ bi okuta ẹfun ti a lù wẹwẹ, igbó ati ere-õrun kì yio dide duro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí èyí báyìí ni ètùtù yóò ṣe wà fún ẹ̀ṣẹ̀ Jákọ́bù, èyí ni yóò sì jẹ́ èṣo kíkún ti ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ: Nígbà tí ó bá mú kí àwọn òkúta pẹpẹ dàbí òkúta ẹfun tí a fọ́ sí wẹ́wẹ́, kì yóò sí ọ̀pá Áṣérà tàbí pẹpẹ tùràrí tí yóò wà ní ìdúró.