Isaiah 28:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Adé ìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Efuraimu gbé! Ẹwà ògo rẹ̀ tí ń ṣá bí ìtànná náà gbé! Ìlú tí ó wà ní òkè àfonífojì dáradára, ohun àmúyangàn fún àwọn tí ó mutí yó.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
EGBE ni fun ade igberaga, fun awọn ọmuti Efraimu, ati fun itàna rirọ ti ogo ẹwà rẹ̀, ti o wà lori afonifoji ọlọra ti awọn ti ọti-waini pa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ègbé ni fún òdòdó-ẹ̀yẹ náà, tí í ṣe ìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Éfáímù, àti sí òdòdó náà tí ń rọ, tí í ṣe ògo ẹwàa rẹ̀, tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú àti sí ìlú náà ìgbéraga àwọn tí a rẹ̀ sílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ wáìnì!