Isaiah 28:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà ọ̀rọ̀ OLUWA sí wọn yóo jẹ́ tòfin-tòfin, èyí òfin tọ̀hún ìlànà. Díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn-ún, kí wọ́n baà lè lọ ṣubú sẹ́yìn kí wọ́n sì fọ́ wẹ́wẹ́; kí á lè dẹ tàkúté sílẹ̀ fún wọn, kí ọwọ́ lè tẹ̀ wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ọ̀rọ Oluwa jẹ aṣẹ le aṣẹ, aṣẹ le aṣẹ fun wọn: ẹsẹ le ẹsẹ, ẹsẹ le ẹsẹ; diẹ nihin, diẹ lọhun: ki nwọn ba le lọ, ki nwọn si ṣubu sẹhin, ki nwọn si ṣẹ́, ki a si dẹ wọn, ki a si mu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fún ìdí èyí, ọ̀rọ̀ OLÚWA sí wọn yóò di pé ṣe kí o ṣe, ṣe kí o ṣe, àṣẹ lé àṣẹ, àṣẹ lé àṣẹ; díẹ̀ níhìnín, díẹ̀ ní ọ̀hún bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò lọ tí wọn yóò tún ṣubu ṣẹ́yìn, wọn yóò farapa, wọn yóò bọ́ sínú okùn a ó sì gbá wọn mú.