Isaiah 28:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí ẹ wí pé: “A ti bá ikú dá majẹmu, a sì ti bá ibojì ṣe àdéhùn. Nígbà tí jamba bá ń bọ̀, kò ní dé ọ̀dọ̀ wa; nítorí a ti fi irọ́ ṣe ibi ìsádi wa, a sì ti fi èké ṣe ibi ààbò.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ẹnyin ti wipe, Awa ti ba ikú dá majẹmu, a si ti ba ipò-okú mulẹ: nigbati pàṣan gigun yio là a já, kì yio de ọdọ wa: nitori awa ti fi eké ṣe ãbo wa, ati labẹ irọ́ li awa ti fi ara wa pamọ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ fọ́n pé, “Àwa ti bá ikú mulẹ̀, pẹ̀lú ibojì ni àwa ti jọ ṣe àdéhùn. Nígbà tí ìbáwí gbígbóná fẹ́ kọjá, kò le kàn wá lára, nítorí a ti fi irọ́ ṣe ààbò o wa àti àìṣòtítọ́ ibi ipamọ́ wa.”