Isaiah 28:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ni n óo fi ṣe okùn ìwọnlẹ̀, òdodo ni n óo fi ṣe ìwọ̀n ògiri.” Òjò àdàpọ̀ mọ́ yìnyín yóo gbá ibi ààbò irọ́ dànù, omi yóo sì bo ibi tí wọ́n sápamọ́ sí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Idajọ li emi o fi le ẹsẹ pẹlu, ati ododo li emi o fi lé òṣuwọn: yinyín yio gbá ãbo eke lọ, omi o si kún bò ibi isasi mọlẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò fi ìdájọ́ ṣe okùn òṣùwọ̀n àti òdòdó òjé òṣùwọ̀n; yìnyín yóò gbá ààbò yín dànù àti irọ́, omi yóò sì kún bo gbogbo ibi tí ẹ ń farapamọ́ sí mọ́lẹ̀.