Isaiah 28:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Majẹmu tí ẹ bá ikú dá yóo wá di òfo, àdéhùn yín pẹlu ibojì yóo sì di asán. Nígbà tí jamba bá ń ṣẹlẹ̀ káàkiri, yóo máa dé ba yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Majẹmu nyin ti ẹ ba ikú dá li a o sọ di asan, imulẹ nyin pẹlu ipò-okú kì yio duro; nigbati paṣán gigun yio rekọja; nigbana ni on o tẹ̀ nyin mọlẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Májẹ̀muu yín tí ẹ bá ikú dá ni a ó fagi lé; àdéhùn yín pẹ̀lú ibojì ni kì yóò dúró. Nígbà tí ìbínú gbígbóná náà bá fẹ́ kọjá, a ó ti ipa rẹ̀ lù yín bolẹ̀.