Isaiah 28:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà ẹ má ṣe yẹ̀yẹ́, kí á má baà so ẹ̀wọ̀n yín le. Nítorí mo ti gbọ́ ìkéde ìparun, tí OLUWA àwọn ọmọ ogun pinnu láti mú wá sórí ilẹ̀ ayé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nitorina, ẹ máṣe jẹ ẹlẹgàn, ki a má ba sọ ìde nyin di lile; nitori emi ti gbọ́ iparun lati ọdọ Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wá, ti o ti pinnu lori gbogbo ilẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ìsinsìn yìí ẹ dákẹ́ ẹlẹ́yà ṣíṣe, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìdè e yín yóò le sí i; OLÚWA, àní OLÚWA àwọn-ogun ti sọ fún mi nípa àṣẹ ìparun ti ó ti pa lórí gbogbo ilẹ̀ náà.