Isaiah 28:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ṣé ẹni tí ń kọ ilẹ̀ tí ó fẹ́ gbin ohun ọ̀gbìn lè máa kọ ọ́ lọ láì dáwọ́ dúró? Àbí ó lè máa kọ ebè lọ láì ní ààlà?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo ọjọ ni agbẹ̀ ha nroko lati gbìn? on o ha ma tú, a si ma fọ́ ilẹ rẹ̀ bi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àgbẹ̀ kan bá tu ilẹ̀ láti gbìn yóò ha máa tulẹ̀ títí títí ni? Ǹjẹ́ yóò ha máa tu ilẹ̀ kí ó sì máa jọ̀ ọ́ títí lọ bí?