Isaiah 28:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àgbẹ̀ kì í fi òkúta ńlá ṣẹ́ ẹ̀gúsí, bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi kùmọ̀, lu kumini. Ọ̀pá ni wọ́n fí ń lu ẹ̀gúsí; igi lásán ni wọ́n fí ń lu kumini.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori a kò fi ohun-elò pakà dili, bẹ̃ni a kì iyí kẹkẹ́ kiri lori kummini; ṣugbọn ọpá li a ifi pa dili jade, ọgọ li a si fi lù kummini.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A kì í fi òòlù pa káráwé tàbí kẹ̀kẹ́-ẹrù là á fi yí kúmínì mọ́lẹ̀; ọ̀pá ni a fi ń lu káráwé, àti kúmínì pẹ̀lú igi.