Isaiah 28:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọtí waini ń ti àwọn wọnyi, ọtí líle ń mú wọn ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n. Ọtí líle ń ti alufaa ati wolii, ọtí waini kò jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí wọ́n ń ṣe mọ́. Ọtí líle ń mú wọn ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n; wọ́n ń ríran èké, wọ́n ń dájọ́ irọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn pẹlu ti ti ipa ọti-waini ṣìna, ati nipa ọti-lile nwọn ti ṣako; alufa ati wolĩ ti ṣìna nipa ọti-lile, ọti-waini mu wọn daradara, nwọn di aṣako nipa ọti-lile, nwọn ṣìna ninu iran, nwọn kọsẹ ni idajọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ta gbọ̀n ọ́n gbọ̀n ọ́n fún ọtí wáìnì wọ́n pòòrì dànìn fún ọtí bíà, Àwọn àlùfáà àti wòlíì ta gbọ̀n ọ́n gbọ̀n ọ́n fún ọtí bíà wọ́n ta gíẹ́ gíẹ́ fún ọtí wáìnì wọ́n ń lọ́ bìrì bìrì fún ọtí bíà, wọ́n ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n nígbà tí wọ́n ń ríran, wọ́n kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n ń mú ìpinnu wá.