Isaiah 28:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n ń sọ pé, “Ta ni yóo kọ́ lọ́gbọ́n? Ta sì ni yóo jíṣẹ́ náà fún? Ṣé àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọyàn lẹ́nu wọn, àbí àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ já lẹ́nu ọmú?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tani on o kọ́ ni ìmọ? ati tani on o fi oye ẹkọ́ yé? awọn ẹniti a wọ́n li ẹnu-ọmú, ti a si já li ẹnu ọyàn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ta ni ẹni náà tí ó ń gbìyànjú àti kọ́? Ta ni ó sì ń ṣàlàyé ìhìn in rẹ̀ fún? Sí àwọn ọmọdé tí a já lẹ́nu ọmú un wọn, sí àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà lẹ́nu ọmú.