Isaiah 29:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo ìran yìí sì ru yín lójú, bí ọ̀rọ̀ inú ìwé tí a fi èdìdì dì. Nígbà tí wọ́n gbé e fún ọ̀mọ̀wé tí wọ́n ní, “Jọ̀wọ́ bá wa kà á.” Ó ní òun kò lè kà á nítorí pé wọ́n ti fi èdìdì dì í.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iran gbogbo si dabi ọ̀rọ iwe kan fun nyin ti a dí, ti a fi fun ẹnikan ti o mọ̀ ọ kà, wipe, Emi bẹ̀ ọ, kà eyi, ti o si wipe, emi kò le ṣe e; nitori a ti dí i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fún un yín gbogbo ìran yìí kò yàtọ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi èdìdì dì sínú ìwé kíká. Bí ẹ bá sì fún ẹni tí ó lè ka ìwé kíká náà, tí ẹ sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ ka èyí,” òun yóò dáhùn pé, “Èmi kò lè kà á; a ti dì í ní èdìdì.”