Isaiah 29:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn tí wọ́n fi èrò wọn pamọ́ fún OLUWA gbé; àwọn tí iṣẹ́ wọn jẹ́ iṣẹ́ òkùnkùn, tí ń wí pé, “Ta ló rí wa? Ta ló mọ̀ wá?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Egbe ni fun awọn ti nwá ọ̀na lati fi ipinnu buruburu wọn pamọ́ kuro loju Oluwa, ti iṣẹ wọn si wà li okunkun, ti nwọn si wipe, Tali o ri wa? tali o mọ̀ wa?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ègbé ni fún àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun láti fi ètò wọn pamọ́ kúrò lójú OLÚWA, tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ẹ wọn nínú òkùnkùn tí wọ́n sì rò pé, “Ta ló rí wa? Ta ni yóò mọ̀?”