Isaiah 29:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí nígbà tí ó bá rí àwọn ọmọ rẹ̀, tíí ṣe iṣẹ́ ọwọ́ mi láàrin wọn, wọn óo fi ọ̀wọ̀ fún orúkọ mi. Wọn óo bọ̀wọ̀ fún Ẹni Mímọ́ Jakọbu; wọn óo sì bẹ̀rù Ọlọrun Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nigbati on nri awọn ọmọ rẹ̀, iṣẹ́ ọwọ́ mi, li ãrin rẹ̀, nwọn o yà orukọ mi si mimọ́, nwọn o si yà Ẹni-Mimọ Jakobu nì si mimọ́, nwọn o si bẹ̀ru Ọlọrun Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n bá ríi láàrin àwọn ọmọ wọn, àwọn iṣẹ́ ọwọ́ mi, wọn yóò ya orúkọ mi sí mímọ́, wọn yóò tẹ́wọ́gba mímọ́ Ẹni Mímọ́ Jákọ́bù wọn yóò dìde dúró ní ìbọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Ísírẹ́lì.