Isaiah 29:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa bá lá àlá pé òun ń jẹun, tí ó jí, tí ó rí i pé ebi sì tún pa òun, tabi tí ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ́ lá àlá pé òun ń mu omi ṣugbọn tí ó jí, tí ó rí i pé òùngbẹ ṣì ń gbẹ òun, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún ogunlọ́gọ̀ orílẹ̀-èdè tí ń bá Jerusalẹmu jà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si dabi igbati ẹni ebi npa nla alá; si wo o, o njẹun; ṣugbọn o ji, ọkàn rẹ̀ si ṣofo: tabi bi igbati ẹniti ongbẹ ngbẹ nla alá, si wo o, o nmu omi, ṣugbọn o ji, si wo o, o dáku, ongbẹ si ngbẹ ọkàn rẹ̀; gẹgẹ bẹ̃ ni gbogbo ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède yio ri, ti mba oke Sioni jà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
àti bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa ń lá àlá pé òun ń jẹun, ṣùgbọ́n ó jí, ebi rẹ̀ sì wà pẹ̀lúu rẹ̀; àti bí ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ lá àlá pé òun ń mumi, ṣùgbọ́n nígbà tí ó yajú pẹ́ ẹ́, pẹ̀lú òùngbẹ tí kò dáwọ́ dúró ni. Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè tí ń bá òkè Ṣíhónì jà.