Isaiah 3:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wò ó! OLUWA, OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo mú gbogbo àwọn tí àwọn eniyan gbójúlé kúrò, ati àwọn nǹkan tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ní Jerusalẹmu ati Juda. Yóo gba gbogbo oúnjẹ tí wọ́n gbójúlé, ati gbogbo omi tí wọ́n fi ẹ̀mí tẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
KIYESI i, Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun, mu idaduro ati ọpá kuro ninu Jerusalemu ati Juda, gbogbo idaduro onjẹ, ati gbogbo idaduro omi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kíyèsí i, OLÚWA, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, fẹ́ mú ìpèsè àti ìrànlọ́wọ́ kúrò ní Jérúsálẹ́mù àti Júdà gbogbo ìpèsè ounjẹ àti ìpèsè omi