Isaiah 3:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA yóo pe àwọn àgbààgbà ati àwọn olórí àwọn eniyan rẹ̀ siwaju ìtẹ́ ìdájọ́, yóo sọ fún wọn pé; “Ẹ̀yin ni ẹ jẹ ọgbà àjàrà mi run, ohun tí ẹ jí nílé àwọn talaka ń bẹ nílé yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa yio ba awọn agbà enia rẹ̀ lọ sinu idajọ, ati awọn ọmọ-alade inu wọn: nitori ẹnyin ti jẹ ọ̀gba àjara nì run: ẹrù awọn talakà mbẹ ninu ile nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA dojú ẹjọ́ kọ àwọn alàgbà àti àwọn olórí àwọn ènìyàn rẹ̀. “Ẹyin ni ẹ ti run ọgbà àjàrà mi, ogún àwọn tálákà ń bẹ̀ nínú ilé yín.