Isaiah 3:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ní, “Nítorí pé àwọn obinrin Jerusalẹmu jẹ́ onigbeeraga, bí wọn bá ń rìn, wọn á gbé ọrùn sókè gangan; wọn á máa ṣẹ́jú bí wọn tí ń yan lọ. Ṣaworo tí ó wà lọ́rùn ẹsẹ̀ wọn a sì máa dún bí wọ́n tí ń gbésẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlupẹlu Oluwa wipe, Nitori awọn ọmọbinrin Sioni gberaga, ti nwọn si nrìn pẹlu ọrùn giga ati oju ifẹkufẹ, ti nwọn nrìn ti nwọn si nyan bi nwọn ti nlọ, ti nwọn si njẹ ki ẹsẹ wọn ró woro:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA wí pé, “Àwọn obìnrin Ṣíónì jẹ́ agbéraga, wọn ń rìn lọ pẹ̀lú ọrùn tí ó nà tàntàn, tí wọn ń fojú pe ọkùnrin, tí wọn ń sọ̀dí bí wọn ti ń yan lọ pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́ tí ń mì wọnjan wọnjan lọ́rùn ẹṣẹ̀ wọn.