Isaiah 3:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn eniyan náà yóo máa fìyà jẹ ara wọn, olukuluku yóo máa fìyà jẹ ẹnìkejì rẹ̀, àwọn aládùúgbò yóo sì máa fìyà jẹ ara wọn. Ọmọde yóo nàró mọ́ àgbàlagbà, àwọn mẹ̀kúnnù yóo máa dìde sí àwọn ọlọ́lá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A o si ni awọn enia lara, olukuluku lọwọ ẹnikeji, ati olukuluku lọwọ aladugbo rẹ̀; ọmọde yio huwà igberaga si àgba, ati alailọla si ọlọla.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn yóò sì má a pọ́n ọmọnìkejì wọn lójú ẹnìkan sí ẹnìkejìi rẹ̀, aládùúgbò sí aládùúgbò rẹ̀. Àwọn ọ̀dọ́ yóò gbogun ti àwọn àgbà, àwọn mẹ̀kúnnù yóò dìde sí bọ̀rọ̀kìnní.