Isaiah 3:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ẹnìkan bá dì mọ́ arakunrin rẹ̀, ninu ilẹ̀ baba rẹ̀, tí ó sọ fún un pé, “Ìwọ ní aṣọ ìlékè, nítorí náà, jẹ́ olórí fún wa; gbogbo ahoro yìí yóo sì wà lábẹ́ àkóso rẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati enia kan yio di arakunrin rẹ̀ ti ile baba rẹ̀ mu, wipe, Iwọ ni aṣọ, mã ṣe alakoso wa, ki o si jẹ ki iparun yi wà labẹ ọwọ́ rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọkùnrin kan yóò di ọ̀kan nínu àwọn arákùnrin rẹ̀ mú nínú ilé baba rẹ̀, yóò sì wí pé, “Ìwọ́ ní aṣọ, ìwọ máa ṣe olórí wa, sì mójútó àwọn ahoro wọ̀nyí!”