Isaiah 30:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní: “Àwọn ọmọ aláìgbọràn gbé. Àwọn tí wọn ń dá àbá tí ó yàtọ̀ sí tèmi, tí wọn ń kó ẹgbẹ́ jọ, ṣugbọn tí kìí ṣe nípa ẹ̀mí mi; kí wọ́n lè máa dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA wipe, egbé ni fun awọn ọlọ̀tẹ ọmọ, ti nwọn gbà ìmọ, ṣugbọn kì iṣe ati ọdọ mi; ti nwọn si mulẹ, ṣugbọn kì iṣe nipa ẹmi mi, ki nwọn ba le fi ẹ̀ṣẹ kún ẹ̀ṣẹ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ègbé ni fún orílẹ̀-èdè alágídí náà,” ni OLÚWA wí, “Fún àwọn tí ó gbé ètò jáde tí kì í ṣe tèmi, tí wọ́n ń gbìmọ̀ pọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa Ẹ̀mí mi, tí wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀;