Isaiah 30:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹgbẹrun ninu yín yóo sá fún ẹyọ ọ̀tá yín kan, gbogbo yín yóo sì sá fún ẹyọ eniyan marun-un títí tí àwọn tí yóo kú ninu yín yóo fi dàbí igi àsíá lórí òkè. Wọn óo dàbí àsíá ati àmì lórí òkè.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹgbẹrun yio sá ni ibawi ẹnikan; ni ibawi ẹni marun li ẹnyin o sá: titi ẹnyin o fi kù bi àmi lori oke-nla, ati bi asia lori oke.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹgbẹ̀rún yóò sá nípa ìdẹ́rùbà ẹnìkan; nípa ìdẹ́rùbà ẹni márùn ún gbogbo yín lẹ ó ṣálọ, tí a ó fi yín sílẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí igi àṣíá ní orí òkè, gẹ́gẹ́ bí àṣíá lórí òkè.”