Isaiah 30:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn oriṣa tí ẹ yọ́ fadaka bò, ati àwọn ère tí ẹ yọ́ wúrà bò yóo di nǹkan èérí lójú yín. Ẹ óo kọ̀ wọ́n sílẹ̀ bí nǹkan aláìmọ́. Ẹ óo sì wí fún wọn pé, “Ẹ pòórá!”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin o si sọ ibora ere fadaka nyin wọnni di aimọ́, ati ọṣọ́ ere wura didà nyin wọnni: iwọ o sọ wọn nù bi ohun-aimọ́, iwọ o si wi fun u pe, Kuro nihinyi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn náà ni ẹ ó ba àwọn ère yín jẹ́ àwọn tí ẹ fi fàdákà bò àti àwọn ère tí ẹ fi wúrà bò pẹ̀lú, ẹ ó sọ wọ́n nù bí aṣọ tí obìnrin fi ṣe nǹkan oṣù ẹ ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ kúrò níbí!”