Isaiah 30:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ wo OLUWA tí ń bọ̀ láti ilẹ̀ òkèèrè, ó ń bọ̀ tìbínú-tìbínú; ninu èéfín ńlá tí ń lọ sókè. Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ kún fún ibinu; ahọ́n rẹ̀ dàbí iná tí ń jóni run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i, orukọ Ọluwa mbọ̀ lati ọ̀na jijin wá, ibinu rẹ̀ si njo, ẹrù rẹ̀ si wuwo: ète rẹ̀ si kún fun ikannu, ati ahọn rẹ̀ bi ajonirun iná:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kíyèsí i, orúkọ OLÚWA ti òkèèrè wá pẹ̀lú ìbínú gbígbóná àti kùrukùru èéfín tí ó nípọn; ètè rẹ̀ kún fún ìbínú ahọ́n rẹ̀ sì jẹ́ iná ajónirun.