Isaiah 30:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Èémí rẹ̀ dàbí odò tí ó ṣàn kọjá bèbè rẹ̀ tí ó lè mu eniyan dé ọrùn. Yóo fi ajọ̀ ìparun jọ àwọn orílẹ̀-èdè, yóo sì fi ìjánu tí ń múni ṣìnà bọ àwọn eniyan lẹ́nu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẽmi rẹ̀ bi kikun omi, yio si de ãrin-meji ọrùn, lati fi kọ̀nkọsọ kù awọn orilẹ-ède: ijanu yio si wà li ẹ̀rẹkẹ́ awọn enia, lati mu wọn ṣina.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èémíi rẹ̀ sì dàbí òjò alágbára, tí ó rú sókè dé ọ̀run. Ó jọ àwọn orílẹ̀ èdè nínú asẹ́ ìparun; ó sì fi sí àgbọ̀n àwọn ènìyàn kókó kan tí ó ń sì wọ́n lọ́nà.