Isaiah 30:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ìró ọ̀pá tí OLUWA yóo fi nà wọ́n yóo dàbí ìró aro ati dùùrù. OLUWA yóo dojú ogun kọ wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati nibi gbogbo ti paṣán ti a yàn ba kọja si, ti Oluwa yio fi lé e, yio ṣe pẹlu tabreti ati dùru: yio si fi irọ́kẹ̀kẹ ogun bá a jà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹgba kọ̀ọ̀kan tí OLÚWA bá gbé lé wọn pẹ̀lú ọ̀pá ìjẹníyà rẹ̀ yóò jẹ́ ti ìlù tamborínì àti ti hápù, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń bá wọn jà lójú ogun pẹ̀lú ẹ̀sẹ́ láti apá rẹ̀.