Isaiah 30:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé a ti pèsè iná ìléru sílẹ̀ láti ìgbà àtijọ́ fún ọba Asiria; iná ńlá tí ń jó pẹlu ọpọlọpọ igi. Èémí OLUWA tó dàbí ìṣàn imí-ọjọ́ ni yóo ṣá iná sí i.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori a ti yàn Tofeti lati igbà atijọ; nitõtọ, ọba li a ti pèse rẹ̀ fun; o ti ṣe e ki o jìn, ki o si gbòro: okiti rẹ̀ ni iná ati igi pupọ; emi Oluwa, bi iṣàn imí-ọjọ́ ntàn iná ràn a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A ti tọ́jú Tófẹ́tì sílẹ̀ tipẹ́tipẹ́, a ti tọ́jú rẹ̀ sílẹ̀ fún ọba. Ojú ààrò rẹ̀ ni a ti gbẹ́ jìn tí ó sì fẹ̀, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ iná àti igi ìdáná; èémí OLÚWA, gẹ́gẹ́ bí ìsàn ṣúfúrù tí ń jó ṣe mú un gbiná.