Isaiah 30:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ẹranko ilẹ̀ Nẹgẹbu nìyí: “Wọ́n di àwọn nǹkan ìní wọn sí ẹ̀yìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, wọ́n sì di ìṣúra wọn sí ẹ̀yìn ràkúnmí. Wọ́n ń la ilẹ̀ ìṣòro ati wahala kọjá. Ilẹ̀ àwọn akọ kinniun ati abo kinniun, ilẹ̀ paramọ́lẹ̀ ati ejò amúbíiná tí ń fò. Wọ́n ń lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan tí kò lè ṣe wọ́n ní anfaani.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọ̀rọ-ìmọ niti awọn ẹranko gusu: sinu ilẹ wahala on àrodun, nibiti akọ ati abo kiniun ti wá, pamọlẹ ati ejò-ina ti nfò, nwọn o rù ọrọ̀ wọn li ejika awọn ọmọ kẹtẹkẹtẹ, ati iṣura wọn lori iké awọn ràkumi, sọdọ awọn enia kan ti kò li ère.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ sí àwọn ẹranko tí ó wà ní Gúúsù: Láàrin ilẹ̀ ìnira àti ìpọ́njú, ti kìnnìún àti abo kìnnìún ti pamọ́lẹ̀ àti ejò olóró, àwọn ikọ̀ náà kó ẹrù àti ọrọ̀ wọn lẹ́yìn àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn ohun ìní wọn ní orí iké àwọn ràkunmí, sí orílẹ̀ èdè aláìlérè,

Recommended Reading