Isaiah 31:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn tí ó ń lọ sí Ijipti fún ìrànlọ́wọ́ gbé! Àwọn tí wọ́n gbójú lé ẹṣin; tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé kẹ̀kẹ́ ogun nítorí pé wọ́n pọ̀, tí wọ́n gbójú lé ẹṣin nítorí pé wọ́n lágbára! Wọn kò gbójú lé Ẹni Mímọ́ Israẹli, wọn kò sì wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
EGBE ni fun awọn ti o sọkalẹ lọ si Egipti fun iranlọwọ; ti nwọn gbẹkẹlẹ ẹṣin, ti nwọn gbiyèle kẹkẹ́, nitoriti nwọn pọ̀: nwọn si gbẹkẹle ẹlẹṣin nitoriti nwọn li agbara jọjọ; ṣugbọn ti nwọn kò wò Ẹni-Mimọ Israeli, nwọn kò si wá Oluwa!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ègbé ni fún àwọn tí ó ṣọ̀kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì fún ìrànwọ́, tí wọn gbẹ́kẹ̀lée eṣin tí wọ́n fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn àti agbára ńlá àwọn ẹlẹ́ṣin wọn, ṣùgbọ́n ti wọn kò bojúwo Ẹni-Mímọ́ Ísírẹ́lì n nì, tàbí kí wọn wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ OLÚWA.