Isaiah 31:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Eniyan sá ni àwọn ará Ijipti, wọn kìí ṣe Ọlọrun. Ẹranko lásán sì ni ẹṣin wọn wọn kì í ṣe àǹjọ̀nnú. Bí OLUWA bá na ọwọ́, tí ó bá gbá wọn mú, ẹni tí ń ranni lọ́wọ́ yóo fẹsẹ̀ kọ, ẹni tí à ń ràn lọ́wọ́ yóo ṣubú; gbogbo wọn yóo sì jọ ṣègbé pọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori enia li awọn ara Egipti, nwọn kì iṣe Ọlọrun; ẹran li awọn ẹṣin wọn, nwọn kì si iṣe ẹmi. Oluwa yio si nà ọwọ́ rẹ̀, ki ẹniti nràn ni lọwọ ba le ṣubu, ati ki ẹniti a nràn lọwọ ba lè ṣubu, gbogbo wọn o jùmọ ṣegbe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ènìyàn ṣáà ni àwọn ará Éjíbítì wọn kì í ṣe Ọlọ́run; ẹran ara ni àwọn ẹṣin wọn, kì í ṣe ẹ̀mí. Nígbà tí OLÚWA bá na ọwọ́ọ rẹ̀ jáde, ẹni náà tí ó ń ṣèrànwọ́ yóò kọṣẹ̀, ẹni náà tí à ń ràn lọ́wọ́ yóò ṣubú; àwọn méjèèjì yóò sì jùmọ̀ parun.