Isaiah 31:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí OLUWA sọ fún mi pé, “Bí kinniun tabi ọmọ kinniun ti máa ń kùn lórí ẹran tí ó bá pa, tí kìí bìkítà fún igbe àwọn olùṣọ́ aguntan, tí wọ́n pera wọn jọ, tí wọn ń bọ̀, tí ẹ̀rù ariwo wọn kìí sìí bà á; bẹ́ẹ̀ ni OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo sọ̀kalẹ̀, yóo wá jà lórí òkè Sioni ati àwọn òkè tí ó yí Sioni ká.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bayi li Oluwa ti wi fun mi pe, Gẹgẹ bi kiniun ati ẹgbọ̀rọ kiniun ti nkùn si ohun-ọdẹ rẹ̀, nigbati a npè ọpọlọpọ oluṣọ́-agutan jade wá si i, ti on kò bẹ̀ru ohùn wọn, ti kò si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ fun ariwo wọn: bẹ̃li Oluwa awọn ọmọ-ogun yio sọkalẹ wá lati jà lori okè-nla Sioni, ati lori oke kékèké rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni ohun tí OLÚWA sọ fún mi: “Gẹ́gẹ́ bí i kìnnìún ti í ké àní kìnnìún ńlá lórí ẹranànjẹ rẹ̀ bí a tilẹ̀ rí ẹgbẹ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàn tí a sì pè wọ́n papọ̀ láti kojúu rẹ̀, ẹ̀rù kò lè bà á pẹ̀lú igbe wọn akitiyan wọn kò sì lè dí i lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun yóò sọ̀kalẹ̀ wá láti jagun lórí òkè Ṣíhónì àti lórí ibi gíga rẹ̀.