Isaiah 31:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí àwọn ẹyẹ tií da ìyẹ́ bo ìtẹ́ wọn, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo dáàbò bo Jerusalẹmu, yóo dáàbò bò ó, yóo sì gbà á sílẹ̀ yóo dá a sí, yóo sì yọ ọ́ kúrò ninu ewu.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gẹgẹ bi ẹiyẹ iti fi iyẹ́ apa ṣe, bẹ̃ni Oluwa awọn ọmọ-ogun yio dabòbo Jerusalemu; ni didãbòbo o pẹlu yio si gbà o silẹ; ni rirekọja on o si dá a si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹyẹ ti ń rábàbà lókè OLÚWA àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bò Jérúsálẹ́mù, Òun yóò dáàbò bò ó yóò sì tú u sílẹ̀ Òun yóò ré e kọjá yóò sì gbà á sílẹ̀.”