Isaiah 31:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Idà ni yóo pa Asiria, ṣugbọn kì í ṣe láti ọwọ́ eniyan; idà tí kò ní ọwọ́ eniyan ninu ni yóo pa á run. Yóo sá lójú ogun, a óo sì kó àwọn ọmọkunrin rẹ̀ lọ máa ṣiṣẹ́ tipátipá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni ara Assiria na yio ṣubú nipa idà, ti kì iṣe nipa idà ọkunrin, ati idà, ti ki iṣe ti enia yio jẹ ẹ: ṣugbọn on o sá kuro niwaju idà, awọn ọdọmọkunrin rẹ̀ yio ma sìnrú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ásíríà yóò ṣubú lọ́wọ́ idà kan tí kò ti ọwọ́ ènìyàn wá; idà tí kì í ṣe ti ẹ̀dá alààyè ni yóò pa wọ́n. Wọn yóò sì sá níwájú idà náà àti àwọn ọmọkùnrin wọn ni a ó fún ní iṣẹ́ ipá ṣe.