Isaiah 31:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ̀rù yóo ba ọba Asiria, yóo sálọ. Ìpayà yóo mú kí àwọn ọ̀gágun rẹ̀ ju àsíá sílẹ̀. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀, OLUWA tí iná rẹ̀ wà ní Sioni, tí ojú ààrò rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Apata rẹ̀ yio kọja lọ fun ẹ̀ru, awọn olori rẹ̀ yiọ bẹ̀ru asia na, ni Oluwa wi, ẹniti iná rẹ̀ wà ni Sioni, ati ileru rẹ̀ ni Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ibi gíga wọn ni yóò wó lulẹ̀ nítorí ìpayà; nípa ìrísí agbára ogun wọn, àwọn ọ̀gágun wọn yóò wárìrì,” ni OLÚWA wí, ẹni tí iná rẹ̀ ń bẹ ní Ṣíhónì, ẹni tí ìléru rẹ̀ wà ní Jérúsálẹ́mù.