Isaiah 32:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Olukuluku yóo dàbí ibi ààbò nígbà tí ẹ̀fúùfù bá ń fẹ́ ati ibi ìsásí nígbà tí ìjì bá ń jà Wọ́n óo dàbí odò ninu aṣálẹ̀, ati bí ìbòòji àpáta ńlá nílẹ̀ olóoru.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnikan yio si jẹ bi ibi isápamọ́ kuro loju ẹfũfu, ati ãbo kuro lọwọ ijì; bi odo-omi ni ibi gbigbẹ, bi ojiji apata nla ni ilẹ gbigbẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹnì kọ̀ọ̀kan yóò dàbí ìdáàbòbò lọ́wọ́ afẹ́fẹ́ àti ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì, gẹ́gẹ́ bí odò omi nínú aṣálẹ̀ àti òjìji àpáta ńlá ní ilẹ̀ òrùngbẹ.