Isaiah 32:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé aláìgbọ́n ń sọ̀rọ̀ òmùgọ̀, ọkàn rẹ̀ sì ń pète ibi. Ó ń ro bí yóo ṣe hùwà ẹni tí kò mọ Ọlọrun, tí yóo sọ̀rọ̀ ìsọkúsọ sí OLUWA; tí yóo fi ẹni tí ebi ń pa sílẹ̀, láì fún un ní oúnjẹ, tí yóo sì fi omi du ẹni òùngbẹ ń gbẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori eniakenia yio ma sọ isọkusọ, ọkàn rẹ̀ yio si ma ṣiṣẹ aiṣedede, lati ṣe agabàgebe, ati lati ṣì ọ̀rọ sọ si Oluwa, lati sọ ọkàn ẹniti ebi npa di ofo, ati lati mu ki ohun-mimu awọn ti ongbẹ ngbẹ ki o dá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí òmùgọ̀ ṣọ̀rọ̀ òmùgọ̀, ọkàn rẹ̀ kún fún ìwà ibi: òun hùwà àìwà-bí-Ọlọ́run ó sì ń tan àṣìṣe tí ó kan OLÚWA kalẹ̀; ẹni ebi ń pa ló fi sílẹ̀ lófo àti fún àwọn tí òrùngbẹ ń gbẹ ni ó mú omi kúrò.