Isaiah 33:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ̀rù ń ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ó wà ní Sioni; ìjayà mú àwọn ẹni tí kò mọ Ọlọrun. Ta ni ninu wa ló lè gbé inú iná ajónirun? Ta ni ninu wa ló lè gbé inú iná àjóòkú?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ̀ru bà awọn ẹlẹṣẹ̀ ni Sioni; ibẹru-bojo ti mu awọn agabàgebè. Tani ninu wa ti o le gbe inu ajonirun iná? tani ninu wa ti yio le gbe inu iná ainipẹkun?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èrù ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní Ṣíhónì; ìwárìrì bá àwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́: “Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú iná ajónirun? Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú ìjóná àìnípẹ̀kun?”