Isaiah 33:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ bá tọ́, tí ó sì ń sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́, ẹni tí ó kórìíra èrè àjẹjù, tí ó kọ̀, tí kò gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí ó di etí sí ọ̀rọ̀ àwọn tí ń gbèrò ati paniyan, tí ó sì di ojú rẹ̀ kí ó má baà rí nǹkan ibi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹniti nrìn li ododo, ti o si nsọ̀rọ titọ́; ẹniti o gàn ère ininilara, ti o gbọ̀n ọwọ́ rẹ̀ kuro ni gbigbà abẹtẹlẹ, ti o di eti rẹ ni gbigbọ́ ti ẹ̀jẹ, ti o si di oju rẹ̀ ni riri ibi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹni tí ó ń rìn lódodo tí ó ń sọ ohun tí ó tọ́, tí ó kọ èrè tí ó tibi ìlọ́nilọ́wọ́gbà wá, tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí ó di etíi rẹ̀ sí ọ̀tẹ̀ láti pànìyàn tí ó sì di ojúu rẹ̀ sí àtipète ibi