Isaiah 33:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn níbẹ̀ ni OLUWA, ninu ògo rẹ̀, yóo jẹ́ odò ńlá ati odò tí ń ṣàn fún wa; níbi tí ọkọ̀ ọlọ́pọ́n kò lè dé, ọkọ̀ ojú omi kò sì ní lè kọjá níbẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nibẹ ni Oluwa ogo yio ri fun wa, bi ibi odò gbigbòro on odò ṣiṣàn; nibiti ọkọ̀ alajẹ̀ kì yio kọja, bẹ̃ni ọkọ̀ nlanla ki yio là a ja.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Níbẹ̀ ni OLÚWA yóò ti jẹ́ Alágbára kan fún wa. Yóò sì dàbí ibi àwọn odò ńlá ńlá àti odò kéékèèkéé. Kì yóò sí ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú tí yóò kọjá lóríi wọn, ọkọ̀ ojú omi ńlá ni a kì yóò tù lórí wọn.