Isaiah 33:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Okùn òpó-ọkọ̀ rẹ̀ ti tú, kò lè mú òpó-ọkọ̀ náà dáradára ní ipò rẹ̀ mọ́; kò sì lè gbé ìgbòkun dúró. A óo pín ọpọlọpọ ìkógun nígbà náà, kódà, àwọn arọ pàápàá yóo pín ninu rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Okùn opó-ọkọ̀ rẹ tú; nwọn kò le dì opó-ọkọ̀ mu le danin-danin, nwọn kò le ta igbokun: nigbana li a pin ikogun nla; amúkun ko ikogun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo okùn rẹ ni ó ti dẹ̀ Ìgbókùnró kò fìdímúlẹ̀, wọn kò taṣọ agbọ́kọ̀rìn, lẹ́yìn náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkógun ni a ó pín àní arọ pẹ̀lú yóò ru ìkógun lọ.