Isaiah 34:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
àwọn ẹranko ìgbẹ́ ati ìkookò yóo jọ máa gbé ibẹ̀, àwọn ewúrẹ́ igbó yóo máa ké pe ara wọn. Iwin yóo rí ibi máa gbé, yóo sì rí ààyè máa sinmi níbẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ẹran ijù ati awọn ọ̀wawa ni yio pade, ati satire kan yio ma kọ si ekeji rẹ̀; iwin yio ma gbe ibẹ̀ pẹlu, yio si ri ibí isimi fun ara rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ẹran ijù àti àwọn ọ̀wàwà ni yóò pàdé, àti sátírè kan yóò máa kọ sí èkejìí rẹ̀, iwin yóò máa gbé ibẹ̀ pẹ̀lú, yóò sì rí ibi isinmi fún ara rẹ̀.